9 Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ?
10 Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀.
11 Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere.
12 Itẹ́ ogo! ibi giga lati ipilẹsẹ ni ibi ile mimọ́ wa!
13 Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.
14 Wò mi sàn, Oluwa, emi o si sàn! gbà mi là, emi o si là, nitori iwọ ni iyìn mi!
15 Sa wò o, nwọn wi fun mi pe, Nibo ni ọ̀rọ Oluwa wà? jẹ ki o wá wayi.