3 Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ.
4 Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ.
5 Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,
6 Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.
7 Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run.
8 Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn.
9 Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i.