3 Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho.
4 Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi;
5 Nwọn ti kọ́ ibi giga fun Baali pẹlu, lati fi iná sun ọmọkunrin wọn, bi ẹbọ-ọrẹ sisun fun Baali, eyiti emi kò pa laṣẹ lati ṣe, ti emi kò si sọ, tabi ti kò si ru soke ninu mi:
6 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa.
7 Emi o sọ igbimọ Juda ati Jerusalemu di asan ni ibi yi; emi o mu ki nwọn ki o ṣubu niwaju ọta wọn, ati lọwọ awọn ti o nwá ẹmi wọn, okú wọn ni a o fi fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko ilẹ fun onjẹ.
8 Emi o si sọ ilu yi di ahoro, ati ẹ̀gan, ẹnikẹni ti o ba nkọja lọ nibẹ yio dãmu, yio si poṣe nitori gbogbo ìna rẹ̀.
9 Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ.