1 EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi.
2 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi.
3 Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
4 Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi.
5 Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
6 Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
7 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti: