14 Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra.
15 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na.
16 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa.
17 Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin.
18 Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́?
19 Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu:
20 Ibinu Oluwa kì yio pada, titi yio fi ṣe e, titi yio si fi mu iro inu rẹ̀ ṣẹ, li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.