18 Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́?
19 Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu:
20 Ibinu Oluwa kì yio pada, titi yio fi ṣe e, titi yio si fi mu iro inu rẹ̀ ṣẹ, li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.
21 Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ.
22 Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.
23 Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li Oluwa wi, kì iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu?
24 Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?