5 Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
6 Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
7 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti:
8 Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.
9 Si awọn woli. Ọkàn mi ti bajẹ ninu mi, gbogbo egungun mi mì; emi dabi ọmuti, ati ọkunrin ti ọti-waini ti bori rẹ̀ niwaju Oluwa, ati niwaju ọ̀rọ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
10 Nitori ilẹ na kún fun awọn panṣaga; ilẹ na nṣọ̀fọ, nitori egún, pápá oko aginju gbẹ: irìn wọn di buburu, agbara wọn kò si to.
11 Nitori, ati woli ati alufa, nwọn bajẹ; pẹlupẹlu ninu ile mi ni mo ri ìwa-buburu wọn, li Oluwa wi.