5 Jeremiah woli si wi fun Hananiah woli niwaju awọn alufa ati niwaju gbogbo enia, ti o duro ni ile Oluwa pe:
6 Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.
7 Ṣugbọn nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ yi ti mo sọ si eti rẹ ati si eti enia gbogbo.
8 Awọn woli ti o ti ṣaju mi, ati ṣaju rẹ ni igbãni sọ asọtẹlẹ pupọ, ati si ijọba nla niti ogun, ati ibi, ati ajakalẹ-arun.
9 Woli nì ti o sọ asọtẹlẹ alafia, bi ọ̀rọ woli na ba ṣẹ, nigbana ni a o mọ̀ woli na pe, Oluwa rán a nitõtọ.
10 Nigbana ni Hananiah woli mu àjaga kuro li ọrùn Jeremiah woli o si ṣẹ́ ẹ.
11 Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ.