33 Nwọn si ti yi ẹhin wọn pada si mi, kì isi ṣe oju: emi kọ́ wọn, mo ndide ni kutukutu lati kọ́ wọn, sibẹ nwọn kò fetisilẹ lati gbà ẹkọ.
34 Nwọn si gbe ohun irira wọn ka inu ile na, ti a fi orukọ mi pè, lati sọ ọ di aimọ́.
35 Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.
36 Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ilu yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, A o fi le ọwọ ọba Babeli, nipa idà, ati nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ-arun.
37 Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu:
38 Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
39 Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn: