10 Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran.
11 Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi.
12 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀!
13 Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.
14 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ.
15 Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
16 Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.