Jer 34:13-19 YCE

13 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe,

14 Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ.

15 Ẹnyin si yi ọkàn pada loni, ẹ si ti ṣe eyi ti o tọ li oju mi, ni kikede omnira, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀; ẹnyin si ti dá majẹmu niwaju mi ni ile ti a fi orukọ mi pè:

16 Ṣugbọn ẹnyin yipada, ẹ si sọ orukọ mi di ẽri, olukuluku enia si mu ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia iranṣẹbinrin rẹ̀, ti on ti sọ di omnira ni ifẹ wọn, ki o pada, ẹnyin si mu wọn sìn lati jẹ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, fun nyin.

17 Nitorina bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò feti si mi, ni kikede omnira, ẹgbọ́n fun aburo rẹ̀, ati ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀: wò o, emi o kede omnira fun nyin, li Oluwa wi, si idà, si ajakalẹ-àrun, ati si ìyan, emi o si fi nyin fun iwọsi ni gbogbo ijọba ilẹ aiye.

18 Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀,

19 Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na;