18 Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀,
19 Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na;
20 Emi o fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: okú wọn yio si jẹ onjẹ fun awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun awọn ẹranko igbẹ.
21 Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin.
22 Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe.