4 Jeremiah si nwọle o si njade lãrin awọn enia: nitori nwọn kò ti ifi i sinu tubu.
5 Ogun Farao si jade lati Egipti wá: nigbati awọn ara Kaldea ti o dótì Jerusalemu si gbọ́ iró wọn, nwọn lọ kuro ni Jerusalemu.
6 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah, woli wá, wipe,
7 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti.
8 Awọn ara Kaldea yio si tun wá, nwọn o si ba ilu yi jà, nwọn o kó o, nwọn o si fi iná kún u.
9 Bayi li Oluwa wi; Ẹ máṣe tan ọkàn nyin jẹ, wipe, Ni lilọ awọn ara Kaldea yio lọ kuro lọdọ wa: nitoriti nwọn kì yio lọ.
10 Nitori bi o tilẹ jẹ pe, ẹnyin lu gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti mba nyin jà bolẹ, ti o si jẹ pe awọn ọkunrin ti o gbọgbẹ li o kù ninu wọn: sibẹ nwọn o dide, olukuluku ninu agọ rẹ̀, nwọn o si fi iná kun ilu yi.