1 Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri:
2 Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.
3 Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ọkunrin Juda, ati Jerusalemu pe, tú ilẹ titun fun ara nyin, ki ẹ má si gbìn lãrin ẹ̀gun.
4 Ẹ kọ ara nyin ni ilà fun Oluwa, ki ẹ si mu awọ ikọla ọkàn nyin kuro, ẹnyin enia Juda ati olugbe Jerusalemu, ki ikannu mi ki o má ba jade bi iná, ki o si jo tobẹ̃ ti kò si ẹniti o le pa a, nitori buburu iṣe nyin.
5 Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì.
6 Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla.