15 Nitori ohùn kan kede lati Dani wá, o si pokiki ipọnju lati oke Efraimu.
16 Ẹ wi fun awọn orilẹ-ède; sa wò o, kede si Jerusalemu, pe, awọn ọluṣọ-ogun ti ilẹ jijin wá, nwọn si sọ ohùn wọn jade si ilu Juda.
17 Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi.
18 Ìwa rẹ ati iṣe rẹ li o ti mu gbogbo ohun wọnyi bá ọ; eyi ni buburu rẹ, nitoriti o korò, nitoriti o de ọkàn rẹ.
19 Inu mi, inu mi! ẹ̀dun dùn mi jalẹ de ọkàn mi; ọkàn mi npariwo ninu mi; emi kò le dakẹ, Nitoriti iwọ, ọkàn mi, ngbọ́ iro fère, ati idagiri ogun.
20 Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan.
21 Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère?