24 Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ.
25 Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ.
26 Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona.
27 Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan.
28 Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀.
29 Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.
30 Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ.