28 Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀.
29 Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.
30 Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ.
31 Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.