10 Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.
11 Goke lọ si Gileadi, ki o si mu ikunra, iwọ wundia, ọmọbinrin Egipti: li asan ni iwọ o lò ọ̀pọlọpọ õgùn; ọja-imularada kò si fun ọ.
12 Awọn orilẹ-ède ti gbọ́ itiju rẹ, igbe rẹ si ti kún ilẹ na: nitori alagbara ọkunrin ti kọsẹ lara alagbara, ati awọn mejeji si jumọ ṣubu pọ̀.
13 Ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun Jeremiah, woli, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli wá lati kọlu ilẹ Egipti.
14 Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri.
15 Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn.
16 A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.