18 Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: ni ìgba ibẹ̀wo wọn, nwọn o ṣegbe.
19 Ipin Jakobu kò dabi wọn: nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo: Israeli si ni ẹ̀ya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
20 Iwọ ni òlù mi, ohun elo-ogun: emi o fi ọ fọ awọn orilẹ-ède tũtu, emi o si fi ọ pa awọn ijọba run;
21 Emi o si fi ọ fọ ẹṣin ati ẹlẹṣin tũtu; emi o si fi ọ fọ kẹ̀kẹ ati ẹniti o gùn u tũtu;
22 Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu;
23 Emi o si fi ọ fọ oluṣọ-agutan ati agbo-ẹran rẹ̀ tũtu, emi o si fi ọ fọ àgbẹ ati àjaga-malu rẹ̀ tũtu; emi o si fi ọ fọ awọn balẹ ati awọn ijoye tũtu.
24 Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi.