22 Bayi li Oluwa wi, sa wò o, enia kan ti ilu ariwa wá, ati orilẹ-ède nla kan yio ti opin ilẹ aiye dide wá.
23 Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni.
24 Awa ti gbọ́ òkiki eyi na: ọwọ wa di rirọ, ẹ̀dun ti di wa mu, ati irora bi obinrin ti nrọbi.
25 Máṣe lọ si inu oko, bẹ̃ni ki o má si rin oju ọ̀na na, nitori idà ọ̀ta, idagiri wà yikakiri.
26 Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji.
27 Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò.
28 Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe.