12 Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ?
13 Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀.
14 Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn:
15 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro.
16 Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.
17 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.
18 Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade.