2 “Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”
3 Ṣùgbọ́n Jeremáyà dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekáyà,
4 ‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.
5 Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle.
6 Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.
7 Olúwa sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn.’
8 “Síwájú síi, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.