2 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, nibo ni awa o jade lọ? ki iwọ ki o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; awọn ti ikú, si ikú, awọn ti idà, si idà; ati awọn ti ìyan, si ìyan, ati awọn ti igbèkun si igbèkun.
3 Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun.
4 Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu.
5 Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.
6 Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.
7 Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.
8 Awọn opo rẹ̀ o di pipọ ju iyanrin eti okun: emi o mu arunni wa sori wọn, sori iyá ati ọdọmọkunrin li ọjọkanri; emi o mu ifoya ati ìbẹru nla ṣubu lu wọn li ojiji.