1 Ẹ̀ṢẸ Juda ni a fi kalamu irin kọ, a fi ṣonṣo okuta adamante gbẹ ẹ sori walã aiya wọn, ati sori iwo pẹpẹ nyin.
2 Bi awọn ọmọ wọn ba ranti pẹpẹ wọn, ati ere òriṣa wọn, lẹba igi tutu, ati ibi giga wọnni.
3 Oke mi ti o wà ni papa! emi o fi ohun-ini rẹ pẹlu ọrọ̀ rẹ gbogbo fun ijẹ, ati ibi giga rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ yi gbogbo àgbegbe rẹ ka.
4 Iwọ fun ara rẹ ni yio jọ̃ ogún rẹ lọwọ, ti mo ti fi fun ọ, emi o mu ọ sìn awọn ọta rẹ ni ilẹ ti iwọ kò mọ̀ ri: nitoriti ẹnyin ti tinabọ ibinu mi, ti yio jo lailai.
5 Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa!
6 Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀.