14 Wò mi sàn, Oluwa, emi o si sàn! gbà mi là, emi o si là, nitori iwọ ni iyìn mi!
15 Sa wò o, nwọn wi fun mi pe, Nibo ni ọ̀rọ Oluwa wà? jẹ ki o wá wayi.
16 Bi o ṣe ti emi ni, emi kò yara kuro ki emi má ṣe oluṣọ-agutan, lẹhin rẹ, bẹ̃ni emi kò bere ọjọ ipọnju, iwọ mọ̀: eyiti o jade li ète mi, o ti hàn niwaju rẹ.
17 Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi!
18 Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.
19 Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu.
20 Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi.