17 Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi!
18 Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.
19 Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu.
20 Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi.
21 Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu:
22 Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.
23 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́.