10 Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé,‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà.Ẹ ti dàbí i wa.
11 A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú.Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lóríàwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’
12 “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run,ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀!Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀,ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí.
13 Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,‘N óo gòkè dé ọ̀run,n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.
14 N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,n óo wá dàbí Olodumare.’
15 Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;