13 Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,‘N óo gòkè dé ọ̀run,n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.
14 N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,n óo wá dàbí Olodumare.’
15 Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;
17 ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’
18 Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọnolukuluku ninu ibojì tirẹ̀.
19 Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.