15 Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;
17 ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’
18 Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọnolukuluku ninu ibojì tirẹ̀.
19 Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.
20 A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù,nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run,o sì ti pa àwọn eniyan rẹ.Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!
21 Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ runnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn,kí wọn má baà tún gbógun dìde,kí wọn gba gbogbo ayé kan,kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.”