1 Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀,wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni.
2 Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni,wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn,wọ́n ń lọ sókè, sódò,bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.
3 “Gbà wá ní ìmọ̀ràn,máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa.Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá,kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan,bí ẹni pé alẹ́ ni.Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde;má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ.
4 Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín.Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.”Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin,tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.
5 Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà,Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.
6 A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.
7 Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,tí ó ní èso àjàrà ninu.