1 Ọ̀rọ̀ OLUWA sí ilẹ̀ Damasku nìyí:“Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́òkítì àlàpà ni yóo dà.
2 Àwọn ìlú rẹ̀ yóo di àkọ̀tì títí laewọn yóo di ibùjẹ àwọn ẹran,níbi tí àwọn ẹran yóo dùbúlẹ̀,tí ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rùbà wọ́n.
3 Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu,kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku,àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siriayóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli,OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
4 “Tó bá di ìgbà náà,a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀,ọrọ̀ wọn yóo di àìní.