1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí:Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi;nítorí pé Tire ti di ahoro,láìsí ilé tabi èbúté!Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n.
2 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni;àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun,
3 wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,ìkórè etí odò Naili.Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé.
4 Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoninítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ríkì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”
5 Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijiptiàwọn ará Ijipti yóo kérora.