4 Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoninítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ríkì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”
5 Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijiptiàwọn ará Ijipti yóo kérora.
6 Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun.
7 Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!
8 Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.
9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.
10 Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́.