1 Ẹ wò ó! OLUWA yóo fọ́ gbogbo ayé wómúwómúyóo sì sọ ọ́ di ahoro.Yóo dojú rẹ̀ rú,yóo sì fọ́n àwọn eniyan inú rẹ̀ ká.
2 Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa;ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀;ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀;ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà.Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówóni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó.Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó.
3 Ogun yóo kó ilé ayé,yóo di òfo patapata.Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
4 Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ.Ayé ń joró, ó sì ń ṣáàwọn ọ̀run ń joró pẹlu.