2 Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbáratí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.
3 Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéragaàwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.
4 Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdótí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.
5 Ní ọjọ́ náà,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.
6 Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè.
7 Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.
8 Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí