21 Nítorí pé OLUWA yóo dìdebí ó ti ṣe ní òkè Firasi,yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.
22 Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.
23 Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
24 ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìnlè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?
25 Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?
26 Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.
27 Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.