13 OLUWA ní,“Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi,ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí;ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi.Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.
14 Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi,ohun ìyanu tí ó jọni lójú.Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”
15 Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?Ta ló mọ̀ wá?”
16 Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò.Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:“Kò ní ìmọ̀.”
17 Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kùtí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi elésoa óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.
18 Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé,ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀.
19 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA.Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli