15 Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?Ta ló mọ̀ wá?”
16 Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò.Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:“Kò ní ìmọ̀.”
17 Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kùtí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi elésoa óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.
18 Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé,ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀.
19 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA.Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli
20 nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán,àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo;àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun;
21 àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀,tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà,tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan.