20 nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán,àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo;àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun;
21 àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀,tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà,tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan.
22 Nítorí náà, OLUWA tí ó ra Abrahamu pada sọ nípa ilé Jakọbu pé,“Ojú kò ní ti Jakọbu mọ́bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23 Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn,wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu;wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli.
24 Àwọn tí ó ti ṣìnà ninu ẹ̀mí yóo ní òye;àwọn tí ń kùn yóo sì gba ẹ̀kọ́.”