11 Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,kò ní dára fún wọn.Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
12 Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.Ẹ̀yin eniyan mi,àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.
13 OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́
14 OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,yóo sọ fún wọn pé;“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.
15 Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”
16 OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.
17 OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”