4 Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn.
5 Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.
6 Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”
7 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.N kò ní oúnjẹ nílébẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.”
8 Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,Juda sì ti ṣubú.Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀.
9 Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:Wọn kò fi bò rárá.Ègbé ni fún wọn,nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.
10 Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọnnítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.