10 Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ríran mọ.”Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé,“Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́,ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa,kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa.
11 Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà,ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.”
12 Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,ẹ sì gbára lé wọn,
13 nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.
14 Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀,tí ó fọ́ yángá-yángá,tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀,tí a lè fi fọn iná ninu ààrò,tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.”
15 Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀,ẹ óo rí ìgbàlà;bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,ẹ óo lágbára.Ṣugbọn ẹ kọ̀.
16 Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni.Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ.Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn.Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín,wọn óo lè sáré gan-an ni.