17 Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia,ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa,ati igbẹkẹle OLUWA títí lae.
18 Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia,ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà.
19 Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀,a óo sì pa ìlú náà run patapata.
20 Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀,ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri.