13 Rabuṣake bá dìde dúró, ó sì kígbe ní èdè Juda, ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria wí:
14 Ọba ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, nítorí kò ní le gbà yín là.
15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, kí ó máa wí fún yín pé, ‘Dájúdájú OLUWA yóo gbà wá, ọba Asiria kò ní fi ogun kó ìlú yìí.’
16 “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ Hesekaya; nítorí ọba Asiria ní kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia kí ẹ jáde tọ òun wá. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, olukuluku yín ni yóo máa jẹ èso àjàrà ati èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, olukuluku yín yóo sì máa mu omi ninu kànga rẹ̀;
17 títí òun óo fi wá mú yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí ó dàbí ilẹ̀ yín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí, tí oúnjẹ ati ọgbà àjàrà ti pọ̀.
18 Ẹ ṣọ́ra kí Hesekaya má baà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì yín lọ́nà, kí ó máa sọ pé, ‘OLUWA yóo gbà wá.’ Ṣé ọ̀kankan ninu àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ti gba ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Asiria rí?
19 Àwọn oriṣa Hamati ati Aripadi dà? Níbo ni àwọn oriṣa Sefafaimu wà? Ṣé wọn gba àwọn ará Samaria kalẹ̀ lọ́wọ́ mi?