Aisaya 36:8-14 BM

8 Rabuṣake ní, “Mo fẹ́ kí Hesekaya bá oluwa mi, ọba Asiria, ṣe pàṣípààrọ̀ kan, n óo fún un ní ẹgbaa ẹṣin bí ó bá lè rí eniyan tó tí ó lè gùn wọ́n.

9 Báwo ni ó ṣe lè lé ẹni tí ó kéré jù ninu àwọn olórí-ogun oluwa mi pada sẹ́yìn, nígbà tí ó jẹ́ pé Ijipti ni ó gbójú lé pé wọn óo fún un ní kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin?

10 Ẹ bi í pé, ṣé kò mọ̀ pé wíwá tí mo wá láti gbógun ti ìlú yìí ati láti pa á run kò ṣẹ̀yìn OLUWA? OLUWA ni ó sọ fún mi pé kí n lọ gbógun ti ilẹ̀ yìí, kí n sì pa á run.”

11 Nígbà náà ni Eliakimu ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, èdè Aramaiki ni kí o fi bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé àwa náà gbọ́ Aramaiki. Má fi èdè Juda bá wa sọ̀rọ̀ kí àwọn ará wa tí ó wà lórí odi má baà gbọ́.”

12 Ṣugbọn Rabuṣake dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati oluwa yín nìkan ni oluwa mi rán mi pé kí n jíṣẹ́ yìí fún ni? Ṣé kò yẹ kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jókòó lórí odi ìlú yìí fetí wọn gbọ́ pé, ati àwọn ati ẹ̀yin, ẹ ti gbé, ẹ o máa jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara yín, ẹ óo sì máa mu ìtọ̀ yín?”

13 Rabuṣake bá dìde dúró, ó sì kígbe ní èdè Juda, ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria wí:

14 Ọba ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, nítorí kò ní le gbà yín là.