13 Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?”
14 Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA,
15 Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní:
16 “Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé.
17 Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà.
18 Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn,
19 ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run.