25 Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’
26 “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,kí ó di òkítì àlàpà.
27 Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọnmá ní agbára mọ́,kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà.Kí wọ́n dàbí ewé inú okoati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hùbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tíí gbẹ kí ó tó dàgbà.
28 “Mo mọ ìjókòó rẹ.Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ,ati inú tí ò ń bá mi bí.
29 Nítorí pé ò ń bá mi bínú,mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá.
30 “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀.
31 Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso.