8 Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.
9 Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:
10 Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.
11 Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,ati pé n kò ní sí láàyè mọ́láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.
12 A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.
13 Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.
14 Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,mò ń ké igbe arò bí àdàbà.Mo wòkè títí ojú ń ro mí,ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.