1 Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu,ẹ tu àwọn eniyan mi ninu.
2 Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí,a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í.OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
3 Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé,“Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù,ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀.
4 Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.
5 Ògo OLUWA yóo farahàn,gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”
6 Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”Mo bá bèèrè pé,“Igbe kí ni kí n ké?”Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.
7 Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.Dájúdájú koríko ni eniyan.