13 Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA,ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
14 Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye,ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́,tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀,tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án?
15 Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi,ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n.Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè.
16 Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun.
17 Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀,wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n.
18 Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀?
19 Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe;tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bòtí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún?